Dee Love Paragraphs Lifestyle

My Amazing Collection of Yoruba Love Poems

yoruba love poems
Fiesta

Yoruba love poems – In October 2017, I came up with an initiative on Facebook where I reached out to friends and family to drop their love poems in Yoruba Language.

Believe me when I say we’ve got a lot of lovers and individuals with skilled usage of Yoruba language. After reaching out to people who showed tremendous enthusiasm. We came up with these amazing collection of Yoruba love poems.

Let’s start with mine first of all!

Collection of Yoruba Love poem 1

Olólùfẹ mi, àyànfẹ́ mi, enibí okàn mi. Ìfẹ́ rẹ l’ón pamí bí ọtín. Ìwọ ni àárọ̀, ọ̀sán àti alẹ´ mi. Kí ọlọ́run kí óṣọ́ wa ju èní lọ. Àá dàgbà àá darúgbó. T’óbá wa aiyé k’íólọ, t’óbá wu ọ̀run kí ówá. Èmi àti ìrẹ ni, lónìí àti lójojúmọ́. Ìfẹ́ rẹ nimofẹ́ nígbesí aiyé mi. Molè pa erin nítorí rẹ, molè p’ejò nítorí rẹ. Jọ̀wọ́ máshe fimísílẹ̀. Aiyé mi.

Collection of Yoruba Love poem 2

Ololufe to nkan bi Itanna owuro, Ìfé mi sí o lékenkà, ó pakaso, Ó bùáyà, Ó lé góñgó, Ó gontío, Omo ají fi dídùn s’ewà, Omo ají f’olá s’oge, Okàn mi a máa sé gììrìgì, Tí o bá kàn rérìín sí mi, Jé mi ní ‘Òo’, káyé mi lè padà Bò sípó. Bù òñtè tó tokàn wá, Lu létà ìfé mi, Wòó, ñ ò kàn déédé gùn l’órùn, Bí àgbáñréré, Esè mi ò kàn sàdédé tínrín, Bí t’alápàándèdè, Ìrètí olójó gbooro, Ló ñ se okàn mi l’áàárè, Gbó ná, Jé ká seré dé’lè Dùbáí, Ká kúrò nínú ooru àt’èfon, Má sè’yonu owó okò, Bààlû mi làá gbé lo, B’óyá t’ókàn bá bale, Òrò ìfé á wo’tí, Sisí adúmáádán, Tiè wobí, Jíí Wagòònù dúdú minimini, Tó wà níta yen

Writer – Eniitan Akinola

Collection of Yoruba Love poem 3

Ololufe, Jé ka lo ìfé – let’s use love, my love. Kini ohun tii á je, to ‘tun dun, ju Oyin lo? Bii ki ba se ìfé.
Ìfé la’koja òfin, lai si ìfé, kila ba ma pe ni Ololufe? Se’bi ìfé ni ìmúgbòró ibagbepo to se’yemu? Ololufe mi owon, fami mo ra, je ka lo ìfé fun’rawa. Je ka fi ìfé bara wa lo’po. Gègé bi o ti mo, igi kan o le’dagbo se, je ka fimo sokan, Kara o le tuwa gbede-gbede. Aderonke mi ajiun, omoge abe’eyín funfun nene, Omo ajilala òsó, omo aji’fojó gbogbo dara bi egbin, Mò daju, wiipe bi òjò ba’hun ro, ìwo ni, Bi òrùn ba hun ran, ìwô kuku ni. L’ójó gbogbo, nibi gbogbo, ni gbogbo asiko, ati laaye, Kaaye, tire ni mo’hun se, ìwo ni àyò okan mi..Ègàn o pe koyin ma dun, igi ìfé èmi ati ìre kuku nbo wa ruwe dandan.. Mo ni ìfé re, je ka fun ìfé laaye oo.. O’seun onitemi.

Writer – Elufowora Eluyemi Lateef

Collection of Yoruba Love poem 4

Alábàárìn mi..
Ìfẹ́ rẹ̀ sì ọkàn mi dàbi ìtọ̀ṣán tí máa tàn lówùrọ̀..Ní gbogbo ìgbà ni ọkàn mi máa ń ṣe àfẹ́rí rẹ.
Eyín funfun balawu bí Ẹ̀gbọ́n òwú ti ń bẹ lẹ́nu rẹ má ń Dami lọrun ni gbogbo igba.
Ọ̀rọ̀ ìwúrí pẹ̀lú ọlọ́pọlọpọ tí máa jáde lẹ́nu rẹ máa fi mí lọ́kàn balẹ..
Eyin menukun, adumaadan, orelekewa, ẹni bí ọkàn mi, Alábàárìn mi, àyànfẹ́ tí elédùmarè yàn fún mi láti òkè wá. Lábé bó ti lè wù kó rí, Ifè rẹ lookan aya mi kò ní yipin. Modupe lọwọ elédùmarè tó fi obirin tó rẹwà bí ò dodo ṣe Gari tira mi..Ìfẹ́ mi sì ọ kò kò ní apá kejì..Ó réré kii jin, kò má ni ìpẹ̀kun, oókan àyà rẹ ni ibi ìpẹ̀kun ìfẹ́ mi. Ọmọ kúkú ndun kú bẹwe gerugeru. Olódo kan ò tere rẹ, Olódo kan ọ tara ra..Jẹ ki a fi ààyè gba ìfẹ́ laarin ara wa.

Writer – Ilesanmi Kehinde

Collection of Yoruba Love poem 5

Ayọ̀ mi, Ìfé mi, Iyì mi, eyínfúnjowó mi, a gùn tásọ́ọ̀ lò mi.

Mo ti rí ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń pè ní ìfẹ́, ṣùgbọ́n iwo fi ohun tí ife njẹ gangan hàn mí, Ìfẹ́ òtítọ́, ìfẹ́ tó ní adùn, ìdí tí mo fi ń pè ó ní ADÙN ÌFẸ́. Lójò, lérùn, lọ́jọ́ ẹkùn, lọ́jọ́ èrín, ìwọ ni mo rí, mo sọpé fedua tó fi ẹ́ sèjìká fún ọrùn mi tí aṣọ fi ń dúró regi lára mi. Níbikíbi, nígbà kúùgbà ni ìfẹ́ rẹ máa ń mú mi lọ́kàn , mi ò tilè lè ṣàlàyé irú ayò tí mo ní nítorí pé ó nífemi, ìdí gan-an nìyí tí mo fi ń pè é ní AYỌ̀ ÌFẸ́. Bí igbin rẹ bá fà, ìkaraun mi a tẹ̀le nítorí ìwọ lààyò ọkàn mi. Olólùfẹ́, Kò ṣẹ́ni tó lè gbà àkàtà lọ́wọ́ akítí, kò sohun tí yóò wọ àárín wa, lola Èdùmàrè ìfẹ́ wá yoo dale, kò ní bomi lo. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ Olólùfẹ́

Writer – Oyebimpe Olofin

Collection of Yoruba Love poem 6

Ìgbà wo ni ng ó tòó tún ri ọ ọkan mi
Igba wo l’ẹ̀rín-ìn mi ó tóo túń dé’nú
Ojojumọ bi ọdún, ọkọ-ọ mi òpagọ̀ọ̀lọ̀ bí ẹkùn
Jọ̀wọ́ dẹ̀hìn bọ̀ kí o wá gba òdòdó-o rẹ lọ́wọ́ ẹkún

Bí mo ti ró ni mo ró
Mi ò f’ìgbà kankan dá ìfẹ́-ẹ wa l’óró
Igi ire ni mí, èmi kìí ṣè’rókò tíí gbàbọ̀dè
Òjò ìfẹ́ rọ̀ wá kí o gbe Àdàbà tèmi dé
Àlàní Ìkọ́ arẹwà l’ókùnrin

Ikú má ì tíì d’ọjọ o
Bí o bá dá ọjọ kò ní dé
Àìsàn má ì tíì d’óṣù o
Bí o bá dá oṣù kò ní kò
Èmi àt’Ìfẹ́-ẹ̀ mi Obìrin àbíro
Èmi àt’ààyò mi Okunrin àbíyè

Orógùn tuntun ni o rà wá’lé, emí o l’óri orogún
Ìfẹ́ ayérayé ni mo bá wá, èmi ò w’aiyé ogun
T’ípẹ́ n’ìwo àgbò ń mọ́’ri
Ire l’ojú owó-o tiwa yóó máà rí

Writer – Akinade

Collection of Yoruba Love poem 7

Apónbéporé mi òwón
Eléyinjú egé mi àtàtà, bí òkín se yàtò laarin eye ní ìwo yàtò laarin Àwon obirin
Eyín funfun kinikini enu re a ma mu orí mi wú.
Èrín enu re a ma mu inú mi dùn
Òrò enu re a ma fimí lókàn balè
Mo ti wà ìdí ìfé wa, sùgbón èmi kò mo ibi tí o ti wá
Mo dúpé lówó elédùà , tí o fi ó jíñkí mi.
Mo ti r’òkun beeni mo ti r’òsà sùgbón èbúté ìfé re ni okàn mi ti rí ìsinmi
Àyàmó ìfé mi, àrídunnumí, mi kò ní fi ó s’ílè nígbà kánkan
Nítori ookan àyà re ni mo ti r’áyò
Títí ayérayé ni èmi yio ma ké o, tí n o sì ma gè ó.
Oba aláwùràbí ko ni jé kí òtá yà wá
Ìfé wa yio ma gbèru si ni àse elédùà.

Writer – Wale Jayeoba

Collection of Yoruba Love poem 8

Alábàárìn mi..
Ìfẹ́ rẹ̀ sì ọkàn mi dàbi ìtọ̀ṣán tí máa tàn lówùrọ̀..
Ní gbogbo ìgbà ni ọkàn mi máa ń ṣe àfẹ́rí rẹ.
Eyín funfun balawu bí Ẹ̀gbọ́n òwú ti ń bẹ lẹ́nu rẹ má ń Dami lọrun ni gbogbo igba.
Ọ̀rọ̀ ìwúrí pẹ̀lú ọlọ́pọlọpọ tí máa jáde lẹ́nu rẹ máa fi mí lọ́kàn balẹ..
Eyin menukun, adumaadan, orelekewa, ẹni bí ọkàn mi, Alábàárìn mi, àyànfẹ́ tí elédùmarè yàn fún mi láti òkè wá.
Lábé bó ti lè wù kó rí, Ifè rẹ ló’kan àyà mi kò ní yipin.
Modúpẹ́ lọ́wọ́ elédùmarè tó fi obìnrin tó rẹwà bí òdòdó ṣe gàrí tírà mi..
Ìfẹ́ mì sí ọ kò ní apá kejì..
Ò réré kii jin, kò má ni ìpẹ̀kun, oókan àyà rẹ ni ibi ìpẹ̀kun ìfẹ́ mi.
Ọmọ kúkú ndun kú bẹwe gerugeru.
Olódo kan ò tere rẹ, Olódo kan ọ tara ra..
Jẹ ki a fi ààyè gba ìfẹ́ laarin ara wa.

Writer – Omo Iya Ibeji

Collection of Yoruba Love poem 9

ololufe mi, eni okanmi yan….ayanfe temi ni kan….ife re lo ma munu midun….ifemi, oremi, enikeji mi, arewa mi, aya mi, oludamoran mi, okan mi…iwoni kan leni tokan mife

Writer – Oladapo Omolade

ololufe mi ahhh enikejimi eniti mo ma ri tinu mi ma ndun
ololufe mi eni okan miyan
ololufe mi ademi aridun nu mi eni ti mo ma ari tinumia simadun
ololufe eniokan mi yan lari gbogbo agbala

Collection of Yoruba Love poem 10

Oun gbe.
Okan mi o dede p ‘oungbe
Ara a mi o bere si se giri
Oju mi o dede bere sii poyi
Bee si ni ese mi o dede bere sii gbon
Oun gbe okan ni

Ife e re ni oun se mi

Okun ru
Osa n fa
Ife e re n da mi lorun
Jowo pa oun gbe okan mi Aduke

Fi owo o re simi laya
Fi enu u re ko mi li enu
Fi oju ife e re komi ni oju
Jowo pa oun gbe okan mi Aduke

Writer – Bolo Dipo

Collection of Yoruba Love poem 11

Ololufemi toba je ounje mi ba ma je oo bo ba je omi mi oba ma muoo tori iwo gan lokan mi fe mari iwo kan ni mofe majiri ..iwo gan ni mofe mabarin …………..ayan femi …ose jeka jo riri ife papo bi odo ife ba kun mi oma foyaa…ife reninu okanmi otutu bi omi amu ..
ololufemi moni fe re

Writer – Mossi Victoria

Collection of Yoruba Love poem 12

Bi àárè ìfé ba n se mi, edakun e súré tete, e bahun pe olalonpe mi abebi.. Dajudaju, ohun nikan lo le salaye bi ti n se mi, té’nikan o mo.

Lalonpe mi awéléwà, afinju olomoge to hun mohungbe ìfé gbeniyan, lai ròo’tì.

Bi lalonpe ba sòrò, t’èrín tò’yàyà ni.. Ìrìnsí e, nise lo n dani lo’rùn, se ti ihuwasi la’fe so ni, abi aponle t’erú t’omo, LA fe royin? Abebi l’éwà, O n’ìwà, o tun ti ilé ire wáa.

E’wo, Omo alalubarika GBA ni omoge ahunperi yii… Idi aba’jo niyi, ti n o filè kóyán re kere ninu ayé mi, tii ìfé re se n gbile lokan mi lojojumo, abi Kini mo tun fe teledua o se fun mi?? Kosi, Whalai Kosi. Irinajo ìfé emi ati olalonpe, whalai Oba a’déda nikan lo le salaye e o Jere.

Wo, Olalonpe, dajudaju, temi ni tire l’ójó gbogbo, titi ayeraye.. Ololufe ma mi’kan.

Writer – Elufowora Eluyemi Lateef

There you have it, collection of Yoruba love poems. Are you a lover that feels this post is incomplete without your yoruba love poem? Join in the fun, let’s have your love poems published as well. Drop your Yoruba love poem in the comments below.

Who knows, your yoruba love poem could be among the greats!

Related Posts

No Comments

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.